23/06/2026
𝗔𝗞𝗢𝗥𝗜 𝗜𝗪𝗔𝗔𝗦𝗨: 𝗔𝗚𝗕𝗔𝗥𝗔 𝗧𝗢𝗪𝗔 𝗟𝗢𝗥𝗜 𝗔𝗛𝗢𝗡
𝗘𝗦𝗘 𝗕𝗜𝗕𝗘𝗟𝗜: 𝗢𝗪𝗘 𝟏𝟖:𝟐𝟏, 𝗘𝗙𝗘𝗦𝗨 𝟒:𝟐𝟗
ÌWÉ ÒWE 18:21
Ikú ati ìye mbẹ ni ipa ahọn: awọn ẹniti o ba si nlò o yio jẹ ère rẹ̀.
Ahọn Le Kere Sugbon o ni Agbara to Pọ, Nítorí Re, Àwọn Ọrọ Ti a n Fi ahọn wa sọ Jade ṣe koko, o si tun Ṣe Pataki, Oun ni Yio Jẹ Ki Aye wa Dara tabi ki Aye wa tún Dara ni idakeji, o wa Lọwọ wa, Bi a ba Ṣe Lo Si.
Ama Sakiyesi rẹ wipe Ọrọ Ni Ọlọrun Fi Da Aye (Genesis 1:3), O so wipe: Jeki imọlẹ ki o wa, imọlẹ si wa
Pelu Ọrọ Sisọ, Ale gbe Aye Eniyan Dide tabi ki a gbe Eniyan Subu.
EFESU 4:29
Ẹ máṣe jẹ ki ọ̀rọ idibajẹ kan ti ẹnu nyin jade, ṣugbọn iru eyiti o dara fun ẹ̀kọ́, ki o le mã fi ore-ọfẹ fun awọn ti ngbọ́.
Gẹgẹ Bí Kristẹni ati iransẹ Ọlorun, Awọn Eniyan o ka Bibeli Gangan Mọ bayii ooo, Awa ni Bibeli ti Awọn Eniyan nka,
Ohun Mẹta dẹni wọn ka ninu Aye wa
1) Aye nka iwa wa
2) Aye nka Ọrọ Ẹnu Wa
3) Aye nka imura Wa
Nitori Re Lo Se Dara ki a má Ṣọra Lọpọlọpọ Fun Àwọn Ọrọ ti yio ma Ti Ẹnu Wa Jade, ki a má ba Shi awon Eniyan Lọna, Nipasẹ Ọrọ Ẹnu Wa
AWON OHUN MAARUN TO YẸ KI A MỌ NIPA AHỌN WA
1) Ọkan Eniyan Le gba Ọgbẹ Tabi ki o gba Àtúnṣe, Nipa bi a ba Ṣe Lo Ahọn wa.
2) Ọlọrun Da Aye Pẹlu Ọrọ, Eyi Fi han wa wipe Awon Ọrọ ti an Sọ ni itumo Nipele ti Ẹmi.
(Genesis 1:3.......Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà)
3) Ti ao ba Lo Ahọn wa Daradara, ti a ba Lo Ni ilokulo, ti Ao si ni ikora-eni-nijanu, oseese ki a fi ahọn wa tu ijọ, Ẹbi tabi Ajọṣepọ Towa Laarin awọn Eniyan.
(Jakobu 1:26.....Bi ẹnikẹni ba ro pe on nsìn Ọlọrun nigbati kò kó ahọn rẹ̀ ni ijanu, ṣugbọn ti o ntàn ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsin oluwarẹ̀ asan ni)
4) Ahọn Ti a Ba Lo Daradara, Ao ma Fi Soro Alafia, iwosan, oju-rere, isegun, itunu, anu, ibukun, igbega ati aseyori.
5) Jesu Kristi Kọwa Wipe ama Jiyin Gbogbo Oro ti a so ni Ojo ikehin, nitori re, A gbọdọ maa Ṣọra Fun Awon Ọrọ ti yio ma Ti Ẹnu Wa Jade.
(Matthew 12:36......Ṣugbọn mo wi fun nyin, gbogbo ọ̀rọ wère ti enia nsọ, nwọn o jihìn rẹ̀.